Oko Sienna rọ lu tirela ni marosẹ Eko s’Ibadan, eeyan mẹta ku

Lati ọwọọ Adefunkẹ AdebiyiOwurọ kutu ọjọ Ẹti, Furaidee ọgbọnjọ oṣu kẹfa ọdun 2023 yii ni eeyan mẹta ṣe bẹẹ di oloogbe ninu ijamba mọto to waye loju ọna marosẹ Eko s’Ibadan, lasiko ti mọto ayọkẹlẹ Sienna kan lọọ rọlu tirela to n jade bọ lati ibudokọ awọn ọkọ nla naa.

Gẹgẹ bi Florence Okpe to fiṣẹlẹ naa lede lorukọ ẹṣọ alaabo lojuu popo nipinlẹ Ogun, FRSC ṣe ṣalaye, o ni mọto meji ti i ṣe Toyota Sienna to ni nọmba BDG 426HT, ati tirela ti nọmba tiẹ jẹ RNG558XC ni ijamba naa kan.

Ajọ FRSC ṣalaye, pe ọkọ ayọkẹlẹ Sienna ọhun ni awakọ rẹ n sare asapajude, to fi ṣe bẹẹ lọọ kọ lu tirela lagbegbe ileepo Total, loju ọna marosẹ Eko s’Ibadan naa.

Ikọlu ọhun lo fa iku eeyan mẹta lẹsẹkẹsẹ, ti ẹnikan si farapa.Ile igbokusi FOS ni wọn gbe awọn oku naa lọ gẹgẹ bi Okpe ṣe wi, wọn si gbe ẹni to fara-ṣeṣe lọ si ọsibitu jẹnẹra Iṣara.

Ajọ FRSC waa gba awọn awakọ nimọran,pe ki wọn yee sare to n fa iku ojiji lojuu popo.

Bakan naa ni wọn ba ẹbi awọn tijamba naa kan kẹdun iku awọn eeyan wọn.