“Agunbajẹ olodo, ẹnu lasan lodoo wọn. Ibajẹ mi lawọn ti wọn ni mo gbowo lọwọọ Baba Adebutu ati Gomina Dapọ Abiọdun n ṣe o.
“Emi ki i ṣe arebipa, mi o si jẹ ijẹkujẹ lọdọ Alagba Adebutu tabi Dapọ Abiọdun nitori ati ṣiṣẹ fun wọn lasiko ibo.
“Mo mawọn ọmọ oju- o-ri-ọla ri, mo mawọn ti wọn rowo akọkọ laye wọn ti wọn n jo ni gbagede aye, iyẹn ko si lọrọọ temi,mo niṣẹ mi lọwọ, mo si too tile tọ, keeyan kan ma mu mi binu pẹlu ohun ti ko ṣẹlẹ ti wọn n gbe kiri o’’
Iwọnyi lọrọ to ti ẹnu agba oloṣelu nipinlẹ Ogun ninu Egbẹ PDP, Oloye Oluṣẹgun Ṣowunmi, jade lalẹ ọjọ Aje ọsẹ yii ti i ṣe Mọnde, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹfa ọdun 2023 yii, lasiko tawọn akọroyin ledee Yoruba, League of Yoruba Media Practitioners n fọrọ wa a lẹnu wo lori awọn ọrọ kan lori ayelujara.
Tẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni iroyin gbode, pe awọn kan yọ patiẹ ti Oloye Ṣẹgun Ṣowunmi toun naa dupo gomina Ogun ri, nile-ẹjọ majisireeti to wa n’Iṣabọ, l’Abẹokuta, lasiko ti ọkunrin yii lọ sibẹ lati wo bi ẹjọ ti ẹgbẹ PDP Ogun pe tako ijawe olubori Gomina Dapọ Abiọdun yoo ṣe lọ.
Igbẹjọ ni Ṣowunmi ba lọ sibẹ, awọn janduku ni wọn ni wọn bẹrẹ si i fi pankẹrẹ lu u lasiko to fẹẹ wọ ọgba kootu naa, lawọn eeyan kan ba bẹrẹ si i sọ pe awọn to lu oloṣelu pataki naa mọ-ọn-mọ da sẹria fun un ni.
Wọn ni nitori Ṣẹgun gbowo lọwọ Oloye Adebutu Kessington ti i ṣe Baba Ọnarebu Ladi Adebutu, to si tun gba lọwọọ Gomina Dapọ Abiọdun lasiko ipolongo ibo to si dalẹẹ Dapọ Abiọdun ni wọn ṣe fiya jẹ ẹ ni kootu ọhun.
Ọrọ yii lawọn akọroyin ni ki Oloye Ṣẹgun Ṣowunmi to jẹ agbẹnusọ fun Alaaji Atiku Abubakar lasiko ipolongo ibo Aarẹ tan imọlẹ si, ti ọkunrin ọmọ bibi ilu Abẹokuta naa fi fibinu rẹ han sawọn eeyan to n sọrọ naa, o loun ki i jẹ nile oro koun tun lọọ jẹun nile egungun o.
“Nitori pe Baba Adebutu jẹ olowo to maa n fun awọn eeyan lowo ko sọ pe mo lọọ tọrọ owo lọwọọ wọn, owo ti wọn fun mi ki i ṣe owo oṣelu. Ṣebi Baba fun Dapọ Abiọdun naa lowo nla, ohun to ba tọ seeyan, ti wọn ba fun un, iyẹn ki i ṣe ẹṣẹ.
“Eyi to ṣẹlẹ nile-ẹjọ yẹn naa, ki i ṣe pe mo ba ẹnikẹni ja nibẹ, mo fẹẹ wọle, wọn ni ko saaye, pe awọn ti ti geeti, mo dẹ yipada lati maa lọ ni wọn tun bẹrẹ si i lu mi. Ko sẹni ti ko mọ pe PDP lo wọle ibo gomina Ogun ni 2023 yii, ẹjọ naa wa ni kootu,emi dẹ ṣẹṣẹ bẹrẹ si i fi ẹjọọ Dapọ Abiọdun sun ni, mo ṣi maa fi ẹjọ ẹ sun ijọba Amẹrika, gbogbo aye ni ma a rojọ ẹ fun, ati oṣo ati ajẹ.
Bawo lajọṣepọ oun ati Dapọ Abiọdun ni awọn akọroyin tun beere, ṣe Ṣowunmi koriira Gomina naa to bẹẹ ni?
Eyi ni Ṣẹgun dahun si pe oun fẹran Gomina Dapọ Abiọdun gan-an latilẹ, oun ko koriira rẹ rara bo tiẹ jẹ pe ẹgbẹ oṣelu awọn ko papọ, o ni oun ko lọtaa, ọrọ oun bii ọrọ ojo ti ki i bẹni kan ṣọta ni.
O ni ohun to kan ṣẹlẹ ni pe oun ko le ri otitọ ọrọ nilẹ ni toun koun ma sọ, aye ko si fẹ otitọ. Ṣẹgun Ṣowunmi sọ pe ohun to n fa wahala ati aigbọra ẹni ye niyẹn.
Ẹsun ibo rira ti wọn fi kan PDP ni kootu Ogun, Oloye Ṣẹgun Ṣowunmi sọ pe ko ruju rara, nitori ko si orukọ ẹgbẹẹ PDP lorii kaadi ẹlẹgbẹrun mẹwaa owo naira ti wọn ni Oloye Ladi Adebutu ha fawọn eeyan.
O ni kedere ni orukọ Iya Ladi to doloogbe han lori kaadi naa, ifilọlẹ lorukọ iya naa lo si pe e, ko ni nnkan kan i ṣe pẹlu ibo rira rara. Ṣowunmi sọ pe nigba ti ile ẹjọ to ga ju ba da ẹjọ naa, yoo ye awọn ti wọn n ṣiyemeji, pe Ladi lo bori ibo Ogun ninu idibo yii, ati pe APC gan-an lo pin owo, pin raisi fawọn eeyan, ti wọn fowo ra ibo wọn gbogbo.
Njẹ Aarẹ Bọla Tinubu to gbakoso ijọba apapọ n ṣe ohun to yẹ pẹlu awọn igbesẹ rẹ to n gbe yii, awọn to n yan sipo atawọn to n rọ loye. Ṣẹgun Ṣowunmi sọ pe amoye to ni laakaye ni Aarẹ Bọla Tinubu, oun mọ pe o loye lati ṣiṣẹ yii, ṣugbọn alabosi lawọn APC.
“ Ṣe ẹ ri Subsidy ti APC ṣẹṣẹ waa yọ yii, awa PDP la ti kọkọ fẹẹ yọ ọ nigba ijọba Jonathan. Niṣe lawọn APC gbogun ti wa, ti wọn n sọ pe a ko nifẹẹ araalu, ti wọn bẹrẹ si i ṣewọde.
“Ṣe ẹ waa ri i bayii, ọjọ keji ti wọn gbajọba yii ni wọn ti yọ subsidy kuro. Gbese ti awa ko fẹẹ jẹ nigba yẹn ni wọn ko wa si, awa PDP riran ju wọn lọ, a o mọ ohun to yẹ ka ṣe lasiko to yẹ ka ṣe e.
“Awọn ipo ti aarẹ n yan awọn eeyan si bayii gẹgẹ bii Yoruba, awọn ẹka ileefowopamọ agba, kọsitọọmu ati bẹẹ bẹẹ lọ, o yẹ ka pe akiyesi wọn si i, ko ma jọ pe Yoruba ti gbapo, ọdọ ara wọn ni wọn roko si. A o gbọdọ sọ pe nitori Yoruba lo wa nipo ka waa dakẹ nibi ti wọn ba ti n ṣe ohun ti ko tọ. To ba jẹ bẹẹ ni wọn n fọwọ pa Ọbafẹmi Awolọwọ lori lasiko Western Region,ṣe yoo ṣe daadaa to ṣe.
“Gbogbo ibi to ba ti yẹ ka sọ otitọ, emi gẹgẹ bi ẹnikan ko ni i dakẹ o. Awọn ohun to fa iṣubu PDP ninu ibo aarẹ to kọja yii naa, mo maa n kọrin ẹ si wọn leti ni. Bi mo ṣe n fẹnu sọ ọ ni mo n fowo mi ṣatunṣe sawọn mi-in, paapaa nipinlẹ Ogun ti mo ti wa, nitori ọrọ ibẹ jẹ mi logun bii ọrọ Naijiria naa ni. Bii ọrọ awọn ọmọ wa ti wọn n kawọ soke jansẹ mọlẹ ti wọn n ṣe bii ọmọọta kiri igboro, emi ki i dakẹ si i, iru eeyan temi jẹ niyẹn’’
Bẹẹ ni Oloye Ṣẹgun Ṣowunmi wi.