President Bola Tinubu

Idaniloju Wa Ninu Orọ Aarẹ Tinubu Nipa ‘Sọbsidi’ Ori Epo, Nnkan Si Maa Senuure ni Naijiria

Bi Aarẹ Orilẹ-Ede yii, Aṣiwaju Bọla Tinubu ṣe kede awọn eto ti yoo ṣẹgun inira to nkoju awọn ọmọ Naijiria latari owo iranwo ori epo, ‘sọbsidi’, tijọba yọ loṣu meji sẹyin, oloṣelu pataki ninu Egbẹ Oṣelu All Progressives Congress (APC) nipinlẹ Ogun, Ọmọọba Adekunle Adebayọ Ayọọla to tun jẹ oludasilẹ Ọbaruwa Foundation, ti sọ pe ileri ireti ọtun (Renewed Hope) ti Aarẹ ṣe lasiko ipolongo ibo ko gbe; o ni idaniloju wa pe ileri naa yoo wa si imuṣẹ laipẹ rara.

Nigba to nba awọn ọmọ Orilẹ-Ede Naijiria sọrọ lalẹ ọjọ Aje ọsẹ yii, Aarẹ Tinubu loun gba pe ilu le fawọn eeyan, o ni ṣugbọn ki wọn farada a foun lasiko yii lati le jere to pọ ti yoo ju iya asiko yii lọ.

Aarẹ ṣalaye pe laarin oṣu meji pere tijọba oun yọwo iranwọ ori epo yii kuro, ko din ni tiriliọnu kan naira tijọba ti ri fi pa mọ. O ni owo nla bi eyi ṣee lo fun igbaye-gbadun araalu, bawọn ko ba si diju yọwo naa bẹẹ, apo awọn alapapin onijibiti ti wọn n jẹ ninu sọbsidi ni yoo lọ.

Lara awọn eto amayedẹrun ti Aarẹ Tinubu la kalẹ lati koju iṣoro to n koju araalu ni ti awọn ọkọ bọginni to to ẹgbẹrun mẹta niye(3000 CNG buses).

Nina ọgọrun-un kan biliọnu (N100bn) fun iṣẹ agbẹ ati ipese ounjẹ, biliọnu marundinlọgọrin (75b) gẹgẹ bi ẹyawo fawọn onileeṣẹ, ọgọrun-un kan ati mẹẹẹdọgbọn biliọnu ( N125bn) gẹgẹ bi ẹyawo fawọn onileeṣẹ kereje ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Awọn eto tijọba gbe kalẹ yii ni Ọmọọba Ayọọla sọ nipa wọn pe, ” Ọrọ ti Aarẹ sọ jẹ idaniloju pe ko ni i jẹ ki iya jẹ araalu nitori ṣọbsidy tijọba rẹ yọ. O ti fi han lẹẹkan si i pe oun paapaa mọ ohun toju awọn ọmọ Naijiria n ri , idi si niyẹn to fi kede awọn eto irọrun to daju pe yoo ko inira sọbsidi lọ raurau ti yoo tun fi ere pupọ silẹ faraalu lati jẹ.

‘’Ṣe ẹ rohun ti Aarẹ Bọla Tinubu sọ lasiko to n ba gbogbo ọmọ Naijiria sọrọ yẹn, idaniloju gidi lo fi han wa, pe ijọba rẹ yoo mu ileri ireti ọtun (Renewed Hope)ṣẹ lorilẹ-ede yii, ọna to yẹ kijọba tọ ni wọn n tọ. Awa gẹgẹ bi araalu lo ku fun lati maa gbadura, ka si maa ran ijọba yii lọwọ, ka le tibẹ lọ sibi giga to ju eyi lọ.”

Lati ọwọọ Adefunkẹ Adebiyi