Ajagungbalẹ Mẹsan-an Bọ Sọwọ Olọpaa n’Ipinlẹ Ogun

Ile-Iṣẹ Olọpaa Ipinlẹ Ogun ti fidi ẹ mulẹ, pe eeyan mẹsan-an ti wọn jẹ ajagungbalẹ ti wọn si tun nfọna eru gbowo lọwọ awọn eeyan Odosegelu, nitosi Ijẹbu-Ode lọwọ awọn ti tẹ bayii, koda, wọn lawọn ti taari wọn sile ẹjọ.

Atẹjade kan to wa lati ọwọ Alukoro ọlọpaa Ogun, SP Ọmọlọla Odutọla lo forukọ awọn tọwọ ba naa lede, awọn naa si ni: Akeem Rabiu, Ayodele Nureni, Wasiu Ọlamilekan, Abiọdun Adeoye, Samuel Abayọmi, Ṣẹsan Badejọ, Ademọla Ajayi, Babafẹmi Badejọ ati Ọlabayọ Jimọh.

Nigba to n ṣalaye siwaju nipa awọn ajagungbalẹ naa, Odutọla sọ pe ọjọ kin-in-ni oṣu kẹjọ yii lọwọ ba wọn, iyẹn lẹyin ti olobo ta ileeṣẹ ọlọpaa pe awọn ajagungbalẹ naa nfa wahala l’Odosegolu pẹlu awọn nnkan ija oloro.

O ni Oga Olọpaa Ogun pata, CP Abiọdun Alamutu, lo paṣẹ fun ti Ijẹbu-Ode, ACP Ọmọsanyi Adeniyi, bi wọn ṣe dọdẹ awọn eeyan naa lọ niyẹn ti wọn si mu wọn ṣinkun pẹlu awọn nnkan ija ti wọn ni lọwọ. Wọn ba oogun abẹnugọngọ pẹlu oogun oloro lọwọ wọn pẹlu bawọn ọlọpaa ṣe sọ.

Gẹgẹ bi atẹjade ti Odutọla fọwọ si naa ṣe wi,awọn ajagungbalẹ yii ti jẹwọ pe iṣẹ laabi bawọnyi lawọn n ṣe loootọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa Ogun wa fi da awọn araalu loju, pe ikoko ko ni i gba omi, ko gba ẹyin ko tun gba ṣọṣọ lọrọ awọn pẹlu awọn oniṣẹẹbi ẹda to ba fẹẹ fi ipinlẹ Ogun ṣebugbe.

Wọn ni CP Alamutu ti loun yoo maa mu wọn ṣinkun bi ẹ̀mú ti i murin lagbẹde Ogun ni.

Lati ọwọọ Adefunkẹ Adebiyi